Isaiah 8:14-15

14 aÒun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́
ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀
àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú
àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.
15Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,
wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,
okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”
Copyright information for YorBMYO